Agbeyewo Akoonu Awon Tiori Fonoloji ni Ede Yoruba
Loading...
Date
2022-06
Journal Title
Journal ISSN
Volume Title
Publisher
YORÙBÁ: Journal of Yorùbá Studies Association of Nigeria
Abstract
Iṣe ̣́ ìwádìí yìí ṣe àlàyé le ̣́kùn-ún lórí àkóónú tío ̣́rí fono ̣́lo ̣́jì me ̣́ta ní èdè Yorùbá. Àwọn tío ̣́rì náà ni tío ̣́rì Onídàrọ (Generative Phonology), tío ̣́rì Adápelení (Auto-segmental Phonology) àti tío ̣́rì Olùborí akópa (Optimality theory). Àfojúsùn iṣe ̣́ ìwádìí yìí ni láti ṣàlàyé àwọn tío ̣́rì yií ní èdè Yorùbá, èyí tí yóó túbo ̣̀ je ̣́ kó rọrùn si fún àwọn ake ̣́ko ̣̀o ̣́ èdè Yorùbá tí wọn nílò àwọn tío ̣́rì yìí fún ìtúpale ̣̀, pàápàá jùlọ nínú iṣe ̣́ àkànṣe wọn. Èyí ríbe ̣́e ̣̀ níwo ̣̀n ìgbà tó je ̣́ pé bàtà ò sí òde ò yá ni tío ̣́rì je ̣́ fún iṣe ̣́ ìwádìí ajẹmédè. Iṣe ̣́ ìwádìí yìí gùnlé iṣe ̣́ àwọn onímo ̣̀ ìsáájú bí i Chomsky ati Halle (1968), Goldsmith (1978), Prince àti Smolensky (1991) abbl. Díe ̣̀ lára ohun tí a rí fàyọ nínú iṣe ̣́ ìwádìí yìí ni pé àlàyé lórí àwọn òfin fono ̣́lo ̣́jì tí ó ń ṣiṣe ̣́ afárá láàárín ìhun ìpìle ̣̀ àti ìhun òkè afo ̣̀ ni tío ̣́rì onídàrọ fúnka mọ. Bákan náà àlàyé lórí òmìnira àmì ohùn ge ̣́ge ̣́ bí ègé tí ó lè dádúró láì fi ti ègé ìró ṣe ni kókó ohun tí tío ̣́rì adápelení fúnka mo ̣́. Àlàyé wa lórí tío ̣́rì olúborí akópa fìdí re ̣̀ múle ̣̀ pé agbára òté (constraint) àti òǹfà ìsopo ̣̀ (Evaluator) lórí síṣe ̣̀dá afo ̣̀ aṣeégbà ni kókó èrò tío ̣́rì adápelení. Ní ìkádìí, a rọ àwọn onímo ̣̀ èdè láti tubo ̣̀ tẹpẹlẹ mo ̣́ títú àwọn tío ̣́rì ajẹmédè palẹ̣̀ sí èdè Yorùbá láti mú kí kíko ̣́ èdè Yorùbá pe ̣̀lú ìtúpale ̣̀ àwọn èròjà àmúkale ̣̀ fáye ̣̀wò pe ̣̀lú àwọn tío ̣́rì fonolo ̣́jì yìí rọrùn fún àwọn olùko ̣́ àti ake ̣́ko ̣̀o ̣́ èdè Yorùbá.
Description
This work indigenized and nativized selected phonological theories in Yoruba language.
Keywords
Citation
NIL