Ọ̀RỌ̀-ÌṢE ÌYÍSÓDÌ “SÍ” LÉDÈ YORÙBÁ
No Thumbnail Available
Date
2024
Authors
Journal Title
Journal ISSN
Volume Title
Publisher
YORÙBÁ: Journal of Yorùbá Studies Association of Nigeria
Abstract
Àsamọ̀
Oríṣìíríṣìí ọ̀rọ̀-ìṣe ló wà ní èdè Yorùbá. Àbùdá ibi ijẹyọ àti ìtumọ̀ wọn sì wà lọ́wọ́ sàkáání tí wón ti jẹ yọ. Ọ̀rọ̀-ìṣe sí àti wà pàápàá sì wà lára àwọn ọ̀rọ̀ ìṣe wọ̀nyí. Àwón onímọ̀ kan pè wọ́n ní ọ̀rọ̀- ìṣe àfarahẹ, nígbà tí àwọn kan pè wọ́n ní ọ̀rọ̀ ìṣe asolùwà-dàbọ̀ (symmetrical verb). Nínú ìwádìí wa, ọ̀rọ̀-ìṣe ẹlẹ́dà ìyísódì ni sí jẹ́. Ìdí ni pé, nínú gbólóhùn ìyísódì nìkan ni sí ti máa ń jẹ jọ. Lójú tiwa, àwọn ọ̀rọ̀-ìṣe tí wọn máa ń sonígbọ̀wọ́ ara wọn ni sí yìí àti wà tí ó jẹ́ òdì rẹ̀ nínú gbólóhùn ìjọ́hẹn. Nì ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, ibi tí ọ̀kan bá ti jẹ yọ, èkejì kì í sábà jé yọ. Àbùdá ìjẹyọ wọn yìí ṣe pẹ̀kí pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àwọn Yorùbá pé, ọwọ́ ọmọdé ò tó pẹpẹ, tàgbàlagbà ò wọ kèǹgbè. Àmọ́ sá, àwọn sàkáání kan wà tí wà kì í sábà rí bẹ́ẹ̀. Ìdí abájọ níí ṣe pẹ̀lú àbùdá àkànlò tí a ṣàkíyèsí ní àwọn sàkáání tí ìwọ̀núbọ̀nú yìí ti wáyé.
Kókó ọ̀rọ̀: Ọ̀rọ̀-ìṣe, Ọ̀rọ̀-ìṣe àfarahẹ, Ọ̀rọ̀-ìṣe asolùwà-dààbọ̀, Ìyísódì, Àmúlùmọ́là èdè.