Orin Dàdàkúàdà Gẹ́gẹ́ Bí Atọ́nà Ìgbáyégbádùn Láwùjọ

dc.contributor.authorHakeem Olawale
dc.date.accessioned2025-07-15T06:44:38Z
dc.date.available2025-07-15T06:44:38Z
dc.date.issued2025
dc.description.abstractKókó pàtàkì tí iṣẹ́ yìí dá lé lórí ni àgbéyẹ̀wò ìwúlò orin dàdàkúàdà tó jẹ́ ọ̀kan lára orin ìbílẹ̀ Yorùbá ní Ìlọrin nílẹ̀ Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bí atọ́ka ìgbáyégbádùn, ìwà ọmọlúàbí àti ìbágbépọ̀ àlàáfíà láwùjọ wa. Iṣẹ́ yìí ṣàfihàn ìwúlò orin lápapọ̀ nípa onírúurú iṣẹ́ tí a ń fi orin jẹ́ láwùjọ ọmọ ènìyàn. Ó sì ṣe àgbéyẹ̀wò díẹ̀ lára àkóónú orin dàdàkúàdà lára àwọn òjìnmí elérée dàdàkúàdà nílẹ̀ Ìlọrin bíi Jáígbadé Àlàó, Odòlayé Àrẹ̀mú, Ọmọékeé Àmọ̀ó àti Àrẹ̀mú Òsé gẹ́gẹ́ bí àwògbè. Orin dàdàkúàdà lánàá, lónìí àti lọ́la. Àwọn olórin ti a yàn láàyò yìí ni ìpèdè Yorùbá wọn jinlẹ̀ nínú àwọn àwo orin wọn, tó sì kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọgbọ́n àti òye tí ènìyàn lè ṣàmúlò láti tún ọmọlúàbí rẹ̀ ṣe nípa ìhùwàsí èyí tó lè ṣe okùnfà ìbágbépọ̀ àlàáfíà fún ìtẹ̀síwájú àwùjọ. Lóòótọ́ ni àwọn orin mìíràn wà tó jẹ́ ti ìbílẹ̀ Ìlọrin tí a mọ̀ wọ́n mọ̀ bí orin bàlúù, orin wákà, orin kèǹgbè, orin kàkàkí àti bẹ̀ǹbẹ́, orin ọlọ́mọ́-ọba, orin agbè àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, ṣùgbọ́n láàrin obì, ọ̀tọ̀ làá yọ oófúà sí ni ọ̀rọ̀ orin dàdàkúàdà. Iṣẹ́ yìí wa ṣe àtúpalẹ̀ àwọn kókó díẹ̀ nínú àkóónú orin àwọn àṣàyàn olórin dàdàkúàdà náà. Tíọ́rì ìmọ̀-ìbárá-ẹni-gbé-pọ̀ ni a lò láti ṣe àtúpalẹ̀ àwọn kókó atáwùjọṣe tí a ṣàmúlò nínú àwọn orin náà, nítorí pé ìbágbépọ̀ ẹ̀dá wà lára kókó pàtàkì tó ń bí orin kíkọ nínú àwùjọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé ti di ayé ọ̀làjú báyìí tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkọkúkọ orin ti gbòde kan, èyí ni ó fà á tí iṣẹ́ yìí fi ṣàfihàn orin dadakúàdà gẹ́gẹ́ bí ọ̀tọ̀lórìn tí gbígbọ́ rẹ̀ kún fún ọgbọ́n, ìmọ̀ àti òye èyí tó lè ṣàǹfààní fún wa nípa híhu ìwà ọmọlúàbí, ìgbáyégbádùn àti ìbágbépọ̀ àlááfíà, kí àwọn ènìyàn àwùjọ sì má baà gbàgbé ogún rere tó wà nílẹ̀ nínú orin àti àwọn ìpohùn ìbílẹ̀ wa gbogbo. Kókó ọ̀rọ̀: Dàdàkúàdà, Ìgbáyégbádùn, Ọ̀rínkíniwín, Ọmọlúàbí, Àwògbè, Ibágbépọ̀ Àlàáfíà.
dc.identifier.urihttps://kwasuspace.kwasu.edu.ng/handle/123456789/5661
dc.titleOrin Dàdàkúàdà Gẹ́gẹ́ Bí Atọ́nà Ìgbáyégbádùn Láwùjọ
Files
Original bundle
Now showing 1 - 1 of 1
Loading...
Thumbnail Image
Name:
Orin Dàdàkúàdà for Verbal Arts USA.doc
Size:
167.5 KB
Format:
Microsoft Word
Description:
License bundle
Now showing 1 - 1 of 1
Loading...
Thumbnail Image
Name:
license.txt
Size:
1.71 KB
Format:
Item-specific license agreed to upon submission
Description: