Ìlò-Èdè Nínú Àṣàyàn Ewì Àpilẹ̀kọ Tí Àwọn Òǹkọ̀wé-Bìnrin Yorùbá kọ: Olúyẹ́misí Adébọ̀wálé Àti Àrìnpé Adéjùmọ̀ Gẹ́gẹ́ Bí Àpẹẹrẹ
Loading...
Date
2021
Authors
Journal Title
Journal ISSN
Volume Title
Publisher
Abstract
Àṣamọ̀
Púpọ̀ nínú àwọn òǹkọ̀wè-kùnrin ni wọ́n máa ń bu ẹnu àtẹ́ lu ìṣọwọ́lò-èdè àwọn òǹkọ̀wé-bìnrin pé ìlò-èdè wọn kò kúnjú òsùnwọ̀n tó. Iṣẹ́ àpilẹ̀kọ yìí wá gbìyànjú láti ṣe ìtúpalẹ̀ ìṣàmúlò-èdè nínú àṣàyàn ewì Olúyẹ́misí Adébọ̀wálé àti Àrìnpé Adéjùmọ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan kókó-ọ̀rọ̀ wọn. Bákan náà ni a ṣe àfihàn àgbékalẹ̀ ewì àpilẹ̀kọ àwọn òǹkọ̀wé-bìnrin méjèèjì wọ̀nyìí ní ète àti jẹ́ kí á mọ̀ pé àparò kan kò ga jùkan lọ pẹ̀lú ìṣàmúlò èdè wọn. Ìlànà ìwádìí jẹ́ kíka àwọn ewì àpilẹ̀kọ Olúyẹ́misí Adébọ̀wálè àti Àrìnpé Adéjùmọ̀ lọ́rínkínniwín. A sì gbìyànjú láti ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú àwọn akéwì wọ̀nyìí. A ṣe àdàkọ àti àtúpalẹ̀ ọ̀rọ̀ tí a gbà sílẹ̀ lẹ́nu wọn. Ọ̀pọ̀ ìwé tí ó wúlò fún iṣẹ́ yìí ni a yẹ̀wò ní àwọn ilé-ìkàwé kí iṣẹ́ yìí lè kúnjú òṣùwọ̀n. Tíọ́rì ìfojú-ìhun-wò ni a lò láti ṣe ìtúpalẹ̀ ìlò-èdè tí àwọn akéwì obìnrin wọ̀nyìí ṣàmúlò nínú ewì àpilẹ̀kọ wọn. Àtúpalẹ̀ yìí jẹ́ kí a rína rí ìlò-èdè tí àwọn akéwì méjèèjì wọ̀nyìí lò, èyí tó pèsè àlàyé tó gbòòrò fún wa láti gbé ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn akéwì náà lérí òṣùwọ̀n pẹ̀lú ìṣàmúlò-èdè àwọn òǹkọ̀wé-kùnrin akẹgbẹ́ wọn. A wá rí i dájú pé akéwì gidi ni wọ́n, wọn kìí ṣe aláriwo lásán. Àbájáde iṣẹ́ ìwádìí yìí jẹ́ kí a mọ̀ pé kò sí ìpèdè kan tó jẹ́ àdáni fún àwọn òǹkọ̀wé-bìnrin. Ní ìparí, iṣẹ́ yìí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé kò sí bí ọkùnrin ṣe lè lo èdè tí àwọn obìnrin náà kò lè lò ó tí a bá ṣe àfiwé iṣẹ́-ọnà òǹkọ̀wé-bìnrin pẹ̀lú tí òǹkọ̀wé-kùnrin.